Hymn 350 – SALEM t'orun Ilu 'bukun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "SALEM t'orun Ilu 'bukun" (C&S Hymn #350, Yoruba). SALEM t'ọrun Ilu 'bukun, T'o kun fun 'fẹ at'ayọ, Ti a f'okuta aye…

Hymn 350 – SALEM t'orun Ilu 'bukun | C&S Yoruba Hymnary
SALEM t'ọrun Ilu 'bukun, T'o kun fun 'fẹ at'ayọ, Ti a f'okuta aye kọ, Ni ọrun giga loke, Pẹl' ogun angẹli yika, To n sọkalẹ b'iyawo. Lat'ode ọrun lọhun wa, L'o ti wọ asọ ogo, To yẹ ẹni ti o fẹ ọ, A o sin o f'ọkọ rẹ; Gbogbo ita at'odi rẹ, Jẹ kiki ọsọ wura Ilẹkun rẹ n dan fun pearli, Wọn wa ni sisi titi; Awọn olotọ wọ'nu re, Nip'ẹjẹ Olugbala, Awọn to farada 'pọnju, 'Tori orukọ Jesu. Wahala at'ipọnju nla L'o s'okuta rẹ lẹwa; Jesu papa l'Ẹni to wọn, S'ipo ti o gbe dara; Ifẹ inu Rẹ sa ni pe, K'a le s'afin Rẹ lọsọ. Ogo at'ọla fun Baba, Ogo at'ọla fun Ọmọ, Ogo at'ọla fun Ẹmi, Mẹtalọkan titi lai; At' ayérayé Ọkan naa, Bakan naa titi ayé. AMIN

Hymn 350 – SALEM t'orun Ilu 'bukun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia