Hymn 349 – O ti lo, Awosanma | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "O ti lo, Awosanma" (C&S Hymn #349, Yoruba). O ti lọ, Awọsanma, Ti gba kuro loju wa, Soke ọrun nibi ti, Oju wa ko le…

Hymn 349 – O ti lo, Awosanma | C&S Yoruba Hymnary
O ti lọ, Awọsanma, Ti gba kuro loju wa, Soke ọrun nibi ti, Oju wa ko le tẹle; O ti kuro l'ayé yi, O ti de ibi mimọ, Lala at'irora tan Ija tan, o ti sẹgun. O ti lọ, Awa si wa, L'ayé ẹsẹ at'iku; A ni 'sẹ lati se fun, L'ayé t'o ti fi silẹ; K'a si tẹle ọna Rẹ: K'a tẹle tọkantọkan, K'a s'ọta Rẹ di ọrẹ, K'a fi Kristi han n'iwa wa. O ti lọ, Oun ti wi pé, O dara ki Emi lọ,‖ Ni ara sa l'o ya wa: Sugbọn or'ọfẹ Rẹ wa: Oun ni awa ko ri mọ, A ni Olutunu re, Ẹmi Rẹ si jẹ tiwa, Oun n s'agbara wa d'ọtun. O ti lọ, L'ọna kanna, L'o yẹ k'Ijọ Rẹ ma lo: f K'a gbagbe ohun ẹhin, K'a si ma tẹ siwaju, Ọrọ Rẹ ni 'mọlẹ wa, Titi de opin ayé, Nibi ti otọ Rẹ wa, Y'o pese fun alaini. O ti lọ, lẹkan si i, A o tun f'oju wa ri, f O wa bakan naa l'ọrun, Gẹgẹ b'o ti wa l'ayé: N'nu 'bugbe t'o wa nibẹ, Y'o pese aye fun wa, Ninu ayé ti mbọ wa, A o j'ọkan pẹlu Rẹ. O ti lọ, Fun ire wa, Ẹ jẹ ki a duro de; O jinde, ko si nihin, O ti goke re ọrun; Jẹ k'a gb'ọkan wa soke, Sibi ti Jesu ti lọ, Si ọdọ Ọlọrun wa, Nibẹ l'alafia wa. AMIN

Hymn 349 – O ti lo, Awosanma | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia