Hymn 346 – E GB'ori yin soke enu ona | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E GB'ori yin soke enu ona" (C&S Hymn #346, Yoruba). Ẹ GB'ori yin soke ẹnu ọna, K'Oluwa ogo wọle, Ẹni t'O f'ẹjẹ Rẹ…

Hymn 346 – E GB'ori yin soke enu ona | C&S Yoruba Hymnary
Ẹ GB'ori yin soke ẹnu ọna, K'Oluwa ogo wọle, Ẹni t'O f'ẹjẹ Rẹ r'ayé pada O mbọ lati gba 'jọba. Hosannah, ẹyin Ọrun, Halleluyah, eyin Ayé, Orun, Osupa, ẹ wolẹ, Kabiyesi, f'Ọba wa Awa Iran Israel ni Afrika, Ẹ gb'ọla Oluwa ga; Ajagun-molu wa ti goke lọ, Lati lọ pese aye. Hosannah, ẹyin Ọrun, Halleluyah, eyin Ayé, Orun, Osupa, ẹ wolẹ, Kabiyesi, f'Ọba wa Wo, Ọba wa ninu Ọlanla Rẹ, Gun kẹkẹ Ofurufu; Agogo Ọrun pẹlu kọrin Iyin, 'Gba t'Ọba Ogo wọle. Hosannah, ẹyin Ọrun, Halleluyah, eyin Ayé, Orun, Osupa, ẹ wolẹ, Kabiyesi, f'Ọba wa Ọkan mi n fa s'Agbala ayọ na, Nibi ti Kristi gunwa; Odi yika ati Agbala Rẹ, Wura l'a fi se lọsọ. Hosannah, ẹyin Ọrun, Halleluyah, eyin Ayé, Orun, Osupa, ẹ wolẹ, Kabiyesi, f'Ọba wa Agbagba Mẹrinlelogun wolẹ, Pẹlu ade wura wọn; At'awọn Ẹda Alaye mẹrin, Wọn n fi iye fo f'ayọ. Hosannah, ẹyin Ọrun, Halleluyah, eyin Ayé, Orun, Osupa, ẹ wolẹ, Kabiyesi, f'Ọba wa AMIN Hosannah, ẹyin Ọrun, Halleluyah, eyin Ayé, Orun, Osupa, ẹ wolẹ, Kabiyesi, f'Ọba wa

Hymn 346 – E GB'ori yin soke enu ona | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia