Hymn 345 – Olorun goke lo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Olorun goke lo" (C&S Hymn #345, Yoruba). Ọlọrun goke lọ, Pẹlu ariwo nla; Awọn ipe ọrun, Ń fi ayọ Angẹli han, Gbogbo…

Hymn 345 – Olorun goke lo | C&S Yoruba Hymnary
Ọlọrun goke lọ, Pẹlu ariwo nla; Awọn ipe ọrun, Ń fi ayọ Angẹli han, Gbogbo ayé yo, k'ẹ gberin, Ẹ f'ogo fun Ọba Ogo. O j'eniyan layé Ọba wa ni loke; Ki gbogbo ilẹ mọ, Ifẹ nla Jesu wa; Gbogbo ayé yo, k'ẹ gberin, Ẹ f'ogo fun Ọba Ogo. Baba fi agbara, Fun Jesu Oluwa; Ogun Angẹl mbọ Ọ, Oun l'Ọba nla ọrun Gbogbo ayé yo, k'ẹ gberin, Ẹ f'ogo fun Ọba Ogo. L'or'itẹ Rẹ mimọ, O gb'ọpa ododo; Gbogbo ọta Rẹ ni, Yoo ka lo bẹrẹ. Gbogbo ayé yo, k'ẹ gberin, Ẹ f'ogo fun Ọba Ogo. f Ọta Rẹ l'ọta wa, Esu, ayé, ẹsẹ; Sugbọn y'o r'ẹhin wọn, Ijọba Rẹ y'o de, Gbogbo ayé yo, k'ẹ gberin, Ẹ f'ogo fun Ọba Ogo. AMIN Gbogbo ayé yo, k'ẹ gberin, Ẹ f'ogo fun Ọba Ogo.

Hymn 345 – Olorun goke lo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia