Hymn 347 – E GBO iro orin ayo orun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E GBO iro orin ayo orun" (C&S Hymn #347, Yoruba). Ẹ GBỌ iro orin ayọ ọrun, Orin ayọ ti isẹgun Jesu; Gbogbo ọta l'o…
Ẹ GBỌ iro orin ayọ ọrun, Orin ayọ ti isẹgun Jesu; Gbogbo ọta l'o tẹri wọn ba fun, Ẹsẹ, iku, isa oku pẹlu. O setan lati lọ gba ijọba, Fun Baba Ọlọrun ohun gbogbo; O setan lati lọ gba iyin nla, T'o ye Olori-ogun 'gbala wa. Ohun ikanu ni lilo Rẹ, fun Awọn ayanfẹ ọmọ-ẹhin Rẹ, Ẹ mase k ọm'nu l'ọrọ itunu, ‘Emi n lọ pese aye yin silẹ.‘ Ọrun gba lo kuro lẹhin eyi, Awọsanma se Olugbala mọ: Awọn ogun-ọrun ho fun ayọ, Fun bibọ Kristi Oluwa ogo. Ẹ mase ba inu yin jẹ rara, Jesu, ireti wa, yoo tun wa; Yoo wa mu awọn eniyan Rẹ lọ, Sibi ti wọn o ba gbe titi lai. AMIN
Hymn 347 – E GBO iro orin ayo orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia