Hymn 341 – JESU y'o tun wa, ko o lorin | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU y'o tun wa, ko o lorin" (C&S Hymn #341, Yoruba). JESU y'o tun wa, kọ ọ lorin, Fun awọn t'o f'ẹjẹ ra pada, Mbọ wa…

Hymn 341 – JESU y'o tun wa, ko o lorin | C&S Yoruba Hymnary
JESU y'o tun wa, kọ ọ lorin, Fun awọn t'o f'ẹjẹ ra pada, Mbọ wa jọba bi Oluwa ogo, Jesu yoo tun pada wa! Jesu y'o tun pada wa, Jesu y'o tun pada wa, Ho iho ayọ ka ibi gbogbo, Jesu y'o tun pada wa! Jesu y'o tun wa! oku yoo dide, Awọn olufẹ y'o tun 'ra wọn ri; Wọn o papọ sọdọ Rẹ ni sanmọ, Jesu y'o tun pada wa! Jesu y'o tun pada wa, Jesu y'o tun pada wa, Ho iho ayọ ka ibi gbogbo, Jesu y'o tun pada wa! Jesu y'o tun wa fun idasilẹ; Lati f'alafia f'ayé ija; Ẹsẹ ose at'ikanu y'o tan, Jesu y'o tun pada wa. Jesu y'o tun pada wa, Jesu y'o tun pada wa, Ho iho ayọ ka ibi gbogbo, Jesu y'o tun pada wa! Jesu y'o tun wa, otọ l'eyi, Tal'awọn asayan at'olotọ, Ti n sọra, to mura fun ibẹwọ? Jesu y'o tun pada wa! Jesu y'o tun pada wa, Jesu y'o tun pada wa, Ho iho ayọ ka ibi gbogbo, Jesu y'o tun pada wa! Jesu y'o tun wa, ogo fun Baba, Jesu y'o tun wa, ogo fun Ọmọ, Ogo f'Ẹmi Mimọ Jesu ti de, Ogo fun Mẹtalọkan. Jesu y'o tun pada wa, Jesu y'o tun pada wa, Ho iho ayọ ka ibi gbogbo, Jesu y'o tun pada wa! AMIN Jesu y'o tun pada wa, Jesu y'o tun pada wa, Ho iho ayọ ka ibi gbogbo, Jesu y'o tun pada wa!

Hymn 341 – JESU y'o tun wa, ko o lorin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia