Hymn 342 – WO Asegun b'o ti goke | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WO Asegun b'o ti goke" (C&S Hymn #342, Yoruba). WO Asẹgun b'o ti goke, Wo Ọba n'nu ọla Rẹ, Ogun kẹkẹ ofurufu, Lọ…

Hymn 342 – WO Asegun b'o ti goke | C&S Yoruba Hymnary
WO Asẹgun b'o ti goke, Wo Ọba n'nu ọla Rẹ, Ogun kẹkẹ ofurufu, Lọ s'ọrun agbala Rẹ; Gbọ orin awọn Angẹli, Halleluya ni wọn n kọ, Awọn 'lẹkun si si silẹ, Lati gba Ọba ọrun. Tani Ologo ti mbọ yi, T'oun ti ipe jubeli? Oluwa awọn 'mọ-ogun, Oun to ti sẹgun fun wa, O jiya lor'agbelebu, O jinde ninu oku, O sẹgun Esu at'ẹsẹ, Ati gbogbo ọta Rẹ. B'o ti n buk'awọn ọrẹ Rẹ, A gba kuro lọwọ wọn; Bi oju wọn si ti n wo lo, O nu nin'awọsanma; Ẹni t'o ba Ọlọrun rin, T'o si n wasu otitọ, Oun, Enọku wa, l'a gbe lọ S'ile Rẹ loke ọrun. Oun, Aaron wa, gbe ẹjẹ Rẹ, Wọ inu ikele lọ, Josua wa, ti wọ Kenaan, Awọn Ọba ń wariri, A fi 'di ẹya Israel, Mulẹ nibi 'sinmi wọn; Elija wa si fẹ fun wa, N'ilọpo meji Ẹmi. Iwọ ti gbe ara wa wọ, Lọ s'ọw' ọtun Ọlọrun, A si joko nibi giga, Pẹlu Rẹ ninu ogo; Awọn Angẹli mbọ Jesu, Eniyan joko lor' itẹ, Oluwa, b'Iwọ ti goke, Jọ jẹ k'a le goke bẹ. AMIN

Hymn 342 – WO Asegun b'o ti goke | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia