Hymn 340 – O SUN ninu 'boji | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "O SUN ninu 'boji" (C&S Hymn #340, Yoruba). O SUN ninu 'boji, Olugbala mi; O duro d'ọjọ na, O si jinde. Lati 'boji O…
O SUN ninu 'boji, Olugbala mi; O duro d'ọjọ na, O si jinde. Lati 'boji O jinde, Pẹlu 'sẹgun lori ọta Rẹ, O jinde l'asegun lat inu 'boji, O wa lai lati b'awọn tirẹ jọba, O jinde, O jinde, Halleluya, Kristi jinde. Wọn n sọ 'boji lasan, Olugbala mi; Wọn f'ọtẹ tẹ lasan, Oluwa mi. Lati 'boji O jinde, Pẹlu 'sẹgun lori ọta Rẹ, O jinde l'asegun lat inu 'boji, O wa lai lati b'awọn tirẹ jọba, O jinde, O jinde, Halleluya, Kristi jinde. Iku ko n'ipa mọ, Olugbala mi; O si 'boji silẹ, Oluwa mi. Lati 'boji O jinde, Pẹlu 'sẹgun lori ọta Rẹ, O jinde l'asegun lat inu 'boji, O wa lai lati b'awọn tirẹ jọba, O jinde, O jinde, Halleluya, Kristi jinde. AMIN Lati 'boji O jinde, Pẹlu 'sẹgun lori ọta Rẹ, O jinde l'asegun lat inu 'boji, O wa lai lati b'awọn tirẹ jọba, O jinde, O jinde, Halleluya, Kristi jinde.
Hymn 340 – O SUN ninu 'boji | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia