Hymn 328 – Jesu t'o ku, k'o gb'aye la | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Jesu t'o ku, k'o gb'aye la" (C&S Hymn #328, Yoruba). Jesu t'o ku, k'o gb'ayé la, Jinde kuro ninu oku, Nipa agbara Rẹ;…
Jesu t'o ku, k'o gb'ayé la, Jinde kuro ninu oku, Nipa agbara Rẹ; A da silẹ lọwọ iku, O d'igbekun n'igbekun lọ, O ye, k'o ma ku mọ. Ẹyin ọm'Ọlọrun, ẹ wo Olugbala ninu ogo; O ti sẹgun iku; Ma banujẹ, ma bẹru mọ, O n lọ pese ayé fun yin, Yoo mu yin lọ 'le. O f'oju anu at'ifẹ, Wo awọn ti O ra pada; Awọn ni ayọ Rẹ; O ri ayọ at'isẹ wọn, O bẹbẹ ki wọn le sẹgun, Ki wọn ba jọba lai. AMIN
Hymn 328 – Jesu t'o ku, k'o gb'aye la | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia