Hymn 327 – HALLELUYA, Halleluya | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "HALLELUYA, Halleluya" (C&S Hymn #327, Yoruba). HALLELUYA, Halleluya, Ẹ gbe ohun ayọ ga, Ẹ kọ orin inu didun, K'ẹ si…

Hymn 327 – HALLELUYA, Halleluya | C&S Yoruba Hymnary
HALLELUYA, Halleluya, Ẹ gbe ohun ayọ ga, Ẹ kọ orin inu didun, K'ẹ si yin Ọlọrun wa! Ẹni t'a kan m'agbelebu, T'o jiya fun ẹsẹ wa; Jesu Kristi Ọba Ogo, Jinde kuro n'nu oku. Irin idabu sẹ kuro, Kristi ku O si tun ye, O mu iye ati aiku, Wa l'ọrọ ajinde Rẹ, Krist ti sẹgun, awa sẹgun, Nipa agbara nla Rẹ, Awa o jinde pelu Rẹ, A o ba wọ 'nu Ogo. Kristi jinde, akọbi ni, Ninu awọn t'o ti sun, Awọn yi ni y'o ji dide, Ni abọ Rẹ ẹkeji; Ikore ti wọn ti pọn tan, Wọn n reti Olukore, Ẹni ti y'o mu wọn kuro, Ninu isa oku wọn. Awa jinde pẹlu Kristi, To n fun wa l'ohun gbogbo, Ojo, iri, ati ogo, To n tan jade loju Rẹ, Oluwa, b'a ti wa l'ayé, Fa ọkan wa sọdọ Rẹ, K'awọn angẹli sa wa jọ, Ki wọn ko wa d'ọdọ Rẹ. Halleluya, Halleluya! Ogo ni fun Ọlọrun; Halleluya, f'Olugbala, Ẹni t'o sẹgun iku; Halleluya f'Ẹmi Mimọ , Orisun 'fẹ, 'wa mimọ, Halleluya, Halleluya, F'Ọlọrun Mẹtalọkan. AMIN

Hymn 327 – HALLELUYA, Halleluya | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia