Hymn 326 – OLUWA ji l'oto | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA ji l'oto" (C&S Hymn #326, Yoruba). OLUWA ji l'otọ, Ihin na ha s'otọ? Wọn ti ri p'Olugbala ku, Wọn ri l'aye pẹlu.…
OLUWA ji l'otọ, Ihin na ha s'otọ? Wọn ti ri p'Olugbala ku, Wọn ri l'aye pẹlu. fOluwa ji l'ootọ, Otọ ko fẹ ju yi; Anu at'otitọ pade, Ti wọn ti n s'ọta ri. Oluwa ji l'ootọ, Isẹ Rẹ l'o se tan; A da ide onigbọwọ, A sẹ apa iku. Oluwa ji l'ootọ, Boji ko le se mọ; Awọn t'o ku si ji pẹlu, Wọn ki o si ku mọ. AMIN
Hymn 326 – OLUWA ji l'oto | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia