Hymn 323 – Kabo, ojo rere, l'a o ma wi titi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Kabo, ojo rere, l'a o ma wi titi" (C&S Hymn #323, Yoruba). Kabọ, ọjọ rere, l'a o ma wi titi; A sẹtẹ 'ku loni, ọrun di…
Kabọ, ọjọ rere, l'a o ma wi titi; A sẹtẹ 'ku loni, ọrun di tiwa, 'Wọ Oku d'alaye, Ọba tit' ayé! Gbogb' ẹda Rẹ Jesu, ni wọn n juba Rẹ. Kabọ, ọjọ rere, l'a o ma wi titi; A sẹtẹ 'ku loni, ọrun di ti wa. Ẹlẹda, Oluwa, Emi alaye! Lat'ọrun l'o ti bojuwo 'sina wa, Ọm' Ọlọrun papa ni 'Wọ tile se, K'O ba le gba wa la, O di eniyan. Kabọ, ọjọ rere, l'a o ma wi titi; A sẹtẹ 'ku loni, ọrun di ti wa. 'Wọ Oluwa iye, O wa tọ 'ku wo; Lati f'ipa Rẹ han, O sun n'iboji, Wa, Ẹmi Olotọ, si m'ọrọ Rẹ sẹ, Ọjọ kẹta Rẹ de, jinde Oluwa! Kabọ, ọjọ rere, l'a o ma wi titi; A sẹtẹ 'ku loni, ọrun di ti wa. Tu igbekun silẹ, t'Esu de l'ẹwọn, Awọn t'o si subu, jọ gbe wọn dide; F'ojurere Rẹ han; jẹ k'ayé riran, Tun mu 'mọlẹ wa de, ‘Wọ sa ni 'mọlẹ. Kabọ, ọjọ rere,‖ l'a o ma wi titi; A sẹtẹ 'ku loni, ọrun di ti wa. AMIN Kabọ, ọjọ rere,‖ l'a o ma wi titi; A sẹtẹ 'ku loni, ọrun di ti wa.
Hymn 323 – Kabo, ojo rere, l'a o ma wi titi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia