Hymn 324 – JI, ji, okan ayo, ji, ji | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JI, ji, okan ayo, ji, ji" (C&S Hymn #324, Yoruba). JI, ji, ọkan ayọ, ji, ji, Oluwa rẹ jinde; Lọ 'boji Rẹ, k'o si mura,…

Hymn 324 – JI, ji, okan ayo, ji, ji | C&S Yoruba Hymnary
JI, ji, ọkan ayọ, ji, ji, Oluwa rẹ jinde; Lọ 'boji Rẹ, k'o si mura, Ọkan ati kọrin: Gbogbo ẹda l'o si ti ji, Ti wọn n kọrin didun, Itanna 'kini t'o ko tan, Lẹba odo lo hu. Isudẹdẹ ayé y'o lọ, L'ọjọ ajinde yi, Iku ko si mọ n'nu Kristi, Iboji ko n'ipa; Ninu Kristi l'a n wa, t'a n sun T'a n ji, t'a si n dide, Omije t'iku mu ba wa, Ni Jesu y'o nu nu. Ki gbogb' ẹyẹ ati igi, At' itanna ti n tan, Ki wọn sọ ti isẹgun Rẹ, Ati t'ajinde Rẹ, Papa, ẹ gbohun yin soke, Ẹ bu sorin ayọ! Wi pé, 'Iku ti ku'. Ọkan ayọ, ẹ ji, ẹ wa, Oluwa t'o jinde; Ẹ yọ ninu ajinde Rẹ, K'ọrọ Rẹ tu yin n'nu, Ẹ gbohun yin soke, k'ẹ yin, Ẹni t'o ji dide; L'ohun kan ni ka gberin pe Jesu jinde fun mi. AMIN

Hymn 324 – JI, ji, okan ayo, ji, ji | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia