Hymn 322 – OLUWA ji loto | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA ji loto" (C&S Hymn #322, Yoruba). OLUWA ji lotọ, Olugbala dide, O f'agbara Rẹ han, L'o r'ọrun apadi: N'ibẹru…

Hymn 322 – OLUWA ji loto | C&S Yoruba Hymnary
OLUWA ji lotọ, Olugbala dide, O f'agbara Rẹ han, L'o r'ọrun apadi: N'ibẹru nla; awọn ẹsọ, Subu lulẹ, wọn si daku. Wo, ẹgbẹ angẹli, Pade l'ajo kikun; Lati gbọ asẹ Rẹ, Ati la ti juba: Wọn f'ayọ wa, wọn si n fo lọ Lati ọrun si 'boji na. Wọn tutu fo lọ s'ọrun, Wọn mu 'hin ayọ lọ: Gbọ iro orin wọn, Bi wọn si ti n fo lọ, Orin wọn ni, Jesu t'o ku, Ti ji dide, o ji loni. Ẹyin t'a ra pada Ẹ gberin ayọ na: Si gbogbo agbayé, Ẹ ho f'ayọ, Jesu t'o ku, Ti ji dide, ki y'o ku mọ. Kabiyesi! Jesu! T'o f'ẹjẹ Rẹ gba wa; Ki iyin Rẹ jale, Iwọ t'o ji dide: A ba Ọ ji, a si jọba, Pẹlu Rẹ lai: l'oke ọrun. AMIN

Hymn 322 – OLUWA ji loto | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia