Hymn 321 – LO so fun gbogbo aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "LO so fun gbogbo aye" (C&S Hymn #321, Yoruba). LỌ sọ fun gbogbo ayé, Lọ tan ihin ayọ yi; Eti t'o ba gbọ, y'o si, Ọkan…

Hymn 321 – LO so fun gbogbo aye | C&S Yoruba Hymnary
LỌ sọ fun gbogbo ayé, Lọ tan ihin ayọ yi; Eti t'o ba gbọ, y'o si, Ọkan t'o ba gbọ, y'o la. Jesu Olugbala wa, T'a sin, fi 'boji silẹ; Ọlọrun gba ẹbọ Rẹ, Ẹbọ ẹsẹ arayé. O ji lati ma ku mọ, Akọbi awọn t'o sun; Ẹni ti o ba gba a gbọ, Yoo ye, b'o tilẹ ku. Angẹli! Ẹda ọrun, f Ẹ ba arayé gberin, Jesu Oludande ji, Alafia titi lai. AMIN

Hymn 321 – LO so fun gbogbo aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia