Hymn 320 – JESU ye; titi aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU ye; titi aye" (C&S Hymn #320, Yoruba). JESU ye; titi ayé, Ẹru iku ko ba ni mọ; Jesu ye: nitori naa; Isa oku ko…

Hymn 320 – JESU ye; titi aye | C&S Yoruba Hymnary
JESU ye; titi ayé, Ẹru iku ko ba ni mọ; Jesu ye: nitori naa; Isa oku ko n'ipa mọ, Alleluya! Jesu ye: lat'oni lọ, Iku jẹ ọna si iye, Eyi y'o jẹ 'tunu wa, 'Gbat' akoko iku ba de. Alleluya! Jesu ye: fun wa l'O ku, Njẹ Tirẹ ni a o ma se; A o f'ọkan funfun sin, A o f'ogo f' Olugbala, Alleluya! Jesu ye: eyi daju, Iku at'ipa okunkun; Ki y'o le ya ni kuro, Ninu ifẹ nla ti Jesu, Alleluya! Jesu ye; gbogbo 'jọba, L'ọrun, ni ayé di Tirẹ, Ẹ jẹ ki a ma tẹle; Ki a le jọba pẹlu Rẹ Alleluya! AMIN

Hymn 320 – JESU ye; titi aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia