Hymn 319 – ALLELUYA! Alleluya!! Aleluya!!! | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ALLELUYA! Alleluya!! Aleluya!!!" (C&S Hymn #319, Yoruba). ALLELUYA! Alleluya!! Aleluya!!! Ija d'opin, ogun si tan,…

Hymn 319 – ALLELUYA! Alleluya!! Aleluya!!! | C&S Yoruba Hymnary
ALLELUYA! Alleluya!! Aleluya!!! Ija d'opin, ogun si tan, Olugbala jagun 'molu, Orin ayọ la o ma kọ- Alleluya. Gbogbo ipa n'iku ti lo; Sugbọn Kristi f'ogun rẹ ka; Ayé! Ẹ ho iho ayọ- Alleluya. Ọjọ mẹta naa ti kọja: O jinde kuro n'nu oku: Ẹ f'ogo fun Ọlọrun wa- Alleluya. O d'ẹwọn ọrun apadi, O s'ilẹkun ọrun silẹ; Ẹ kọrin iyin 'sẹgun Rẹ- Alleluya. Jesu nipa iya t'o jẹ, Gba wa lọwọ oro iku, K'a le ye, k'a si ma yin Ọ. Alleluya. AMIN

Hymn 319 – ALLELUYA! Alleluya!! Aleluya!!! | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia