Hymn 316 – Sinmi okan mi, ni ireti | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Sinmi okan mi, ni ireti" (C&S Hymn #316, Yoruba). Sinmi ọkan mi, ni ireti: Ma bẹru bi ọla ti le ri, Sa sinmi, iku papa…
Sinmi ọkan mi, ni ireti: Ma bẹru bi ọla ti le ri, Sa sinmi, iku papa l'ọna, Iransẹ Ọba t'a ran si Ọ. Sinmi ọkan mi, Jesu ti ku, Lotọ O si ti jinde pẹlu; Eyi to fun ireti mi, pe Mo ku, mo si ye ninu Jesu. Sinmi ọkan mi, ―O ti pari Jesu pari 'sẹ igbala Rẹ; Sinmi, a ti se gbogbo rẹ tan, Lẹkan lai, igbala di tirẹ. Ogo fun Jesu ti O jinde! ‘Wọ t'a bi, ta pa fun arayé; Ogo fun Mẹtalọkan lailai! Fun Baba, Ọmọ ati Ẹmi. AMIN
Hymn 316 – Sinmi okan mi, ni ireti | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia