Hymn 317 – LO kede ayo na fun gbogbo aye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "LO kede ayo na fun gbogbo aye" (C&S Hymn #317, Yoruba). LỌ kede ayọ na fun gbogbo ayé, P'ọmọ Ọlọrun sẹgun iku: Fi…
LỌ kede ayọ na fun gbogbo ayé, P'ọmọ Ọlọrun sẹgun iku: Fi tiyin-tiyin pel'ayọ royin na fi Ẹmi Mimọ to gunwa. Ọba mi de! asẹgun mi de! Ogo, Ọla at' agbara ati 'pa F' Ọdaguntan to gunwa. Iyin Jesu l'awọn Angeli n ke, T'o wa ra 'rayé pada, Ọkan soso ajanaku ni Jesu, T'o m'ayé pẹlu ọrun. Ọba mi de! asẹgun mi de! Ogo, Ọla at' agbara ati 'pa F' Ọdaguntan to gunwa. Kabiyesi Ọba Alayéluwa, Mẹtalọkan Alagbara, Awamaridi Olodumare, T'o n se isẹ iyanu. Ọba mi de! asẹgun mi de! Ogo, Ọla at' agbara ati 'pa F' Ọdaguntan to gunwa. Itiju nla dabo awọn ika, T'o kan Oluwa wa mọ 'gi, Rikisi ikọkọ ata ti d'asan, Olugbala ji dide. Ọba mi de! asẹgun mi de! Ogo, Ọla at' agbara ati 'pa F' Ọdaguntan to gunwa. Bi orilẹ-ede eniyan dudu, Ati ka wa si eweko, f Sugbọn awa ni Baba kan l'oke, T'o mọ pe 'sẹ Rẹ ni wa. Ọba mi de! asẹgun mi de! Ogo, Ọla at' agbara ati 'pa F' Ọdaguntan to gunwa. Ayọ t'o wa ninu Ajinde, Jọwọ fun wa Olugbala, 'Gba t'a ba yọ si Ọ, Ẹlẹda wa, K'awa le gb'ade ogo. Ọba mi de! asẹgun mi de! Ogo, Ọla at' agbara ati 'pa F' Ọdaguntan to gunwa. Awa f'ogo fun Baba wa l'oke, A tun f'ogo fun Ọmọ Rẹ, Awa tun f'ogo fun Ọ Ẹmi Mimọ Mẹtalọkan l'ọpẹ yẹ. Ọba mi de! asẹgun mi de! Ogo, Ọla at' agbara ati 'pa F' Ọdaguntan to gunwa. AMIN Ọba mi de! asẹgun mi de! Ogo, Ọla at' agbara ati 'pa F' Ọdaguntan to gunwa.
Hymn 317 – LO kede ayo na fun gbogbo aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia