Hymn 315 – ISINMI awon mimo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ISINMI awon mimo" (C&S Hymn #315, Yoruba). ISINMI awọn mimọ, Ọjọ ohun ijinlẹ, Ti Ẹlẹda ti bukun Apẹrẹ isinmi Rẹ, Oluwa…
ISINMI awọn mimọ, Ọjọ ohun ijinlẹ, Ti Ẹlẹda ti bukun Apẹrẹ isinmi Rẹ, Oluwa sinmi 'sẹ Rẹ, O ya 'jọ na si mimọ. Loni oku Oluwa, N sinmi ninu iboji: A ti we l'asọ oku, Lat' ori titi d'ẹsẹ, A si fi okuta se, A si fi edidi di. Oluwa, titi ayé, L'a o ma pa eyi mọ, A o t'ilẹkun pinpin, K'ariwo ma ba wọle, A o fi suru duro, Tit' Iwọ o tun pada. Gbogbo awọn t'o si sun, Wọn o wa ba Ọ sinmi; Wọn o bọ lọwọ lala, Wọn n reti ipe 'kẹhin, T'a o di ẹda titun, T'ayọ wa ki y'o lopin. Jesu yọ wa nin' ẹsẹ, K'a ba le ba wọn wọle, Ewu ati 'sẹ y'o tan, A o f'ayọ goke lọ, A o ri Ọlọrun wa, A o si ma sin lailai. AMIN
Hymn 315 – ISINMI awon mimo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia