Hymn 314 – N'IWAYA 'jakadi / Oun nikan nja | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "N'IWAYA 'jakadi / Oun nikan nja" (C&S Hymn #314, Yoruba). ITAN ORI AGBELEBU GETSMANE N'IWAYA 'jakadi / Oun nikan nja O…

Hymn 314 – N'IWAYA 'jakadi / Oun nikan nja | C&S Yoruba Hymnary
ITAN ORI AGBELEBU GETSMANE N'IWAYA 'jakadi / Oun nikan nja O n fẹ iranlọwọ, / sugbọn ko ri. B'osupa ti n wọ / l'or'oke Olifi, Adura tani n goke / lọrọ yi? Ẹjẹ wo l'eyi ti / n rọ bi ojo Lat'ọkan Rẹ wa, ―Ẹ / ni 'banujẹ? Irora aileso / mbẹ loju Rẹ, Ojiya ti mbẹbẹ, / tan' Iwọ? AMIN ỌNA IKANU GBỌ b'o ti mba ọ sọ / rọ lọkan rẹ, ―Ọmọ ti mo ku fun, / tẹle mi. ―Ki n ma m'ago ti/Baba fun mi bi? 'Gbati mimu rẹ jẹ / 'gbala rẹ? ―A lu, a tutọ si / a fi sẹfẹ, A na, a si de / l'ade ẹgun. ―Mo n lọ si Gọlgọta / nibẹ n ó ku, 'Tor' ifẹ mi si Ọ, / Emi ni. AMIN ỌRỌ MEJE ORI AGBELEBU A KAN mo 'gi ẹsin, / ko ke 'rora O r'ẹru ẹsẹ wa. / Tirẹ kọ. 'Wọ Orun mi, o le / wọ okun bi? Ọrọ wo l'o tẹ / nu Rẹ wa ni? Baba, dariji wọn‖ / l'adura Rẹ Baba si gbọ bi / ti ma gbọ ri. Gbọ bi ole ni ti / n tọrọ anu, Oun se 'leri Pa / radise fun.. Ibatan at'ọrẹ / rọgba yika, Maria oun Magdalen / r'opin rẹ. Meji ninu wọn di / tiyatọmọ, Ọkan t'ọrọ Rẹ / ti sọ d'ọkan. Okunkun bo ilẹ / ọsan d'oru, Isẹju kọja b'/ ọdun pupọ. Gbọ 'gbe 'rora lati / nu okun na, Baba 'Wọ ko mi / silẹ, eese? A! ikọsilẹ nla! / iku ẹgun, Igbe kil' eyi, / ―Oungbẹ n gbẹ mi.‖ Gbọ, ―O ti pari‖ /Ijakadi pin, Iku at' ipoku / a sẹ wọn. Baba, gba ẹmi mi‖ / l'o wi kẹhin; Krist' Oluwa iye / O si ku. AMIN IKESI ỌMỌ 'rora mi ti / mo f'ẹjẹ ra, Mo gba o lọw' esu / f'Ọlọrun. Wa, alarẹ, wa f'ori / l'ayé mi Sa pamọ sọdọ mi, / k'o sinmi. Wa sọdọ Baba mi / wa laibẹru, Alagbawi rẹ,/ wa nitosi. Wa mu ninu ore-ọfẹ Ẹmi: Emi ni ini rẹ / 'Wọ t'emi.‖ AMIN IDAHUN MO f'ara mi fun Ọ/ Oluwa mi Sa f'ifẹ Rẹ 'yebiye / fun mi Gbogb' ohun ti mo ni / t'ara t'ọkan, Nko jẹ fi du ọ, / gba gbogbo rẹ Sa ba mi gbe dopin, /Oluwa mi Jesu Olugbala / Emmanuel, B'akoko Rẹ ba de, / jẹ ki n yin Ọ; Yin Ọ nile Rẹ / titi lailai. AMIN

Hymn 314 – N'IWAYA 'jakadi / Oun nikan nja | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia