Hymn 313 – OLORUN fe araye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN fe araye" (C&S Hymn #313, Yoruba). ỌLỌRUN fẹ arayé, O fẹ to bẹẹ gẹ; T'O ran Ọmọ Re w'ayé, T'O ku fun elẹsẹ:…

Hymn 313 – OLORUN fe araye | C&S Yoruba Hymnary
ỌLỌRUN fẹ arayé, O fẹ to bẹẹ gẹ; T'O ran Ọmọ Re w'ayé, T'O ku fun elẹsẹ: Ọlọrun ti mo tẹle, Pe, emi o sẹ si Ofin ati ifẹ Rẹ, Iwọ ha fẹ mi bi? Lotọ, Ọlọrun fẹ mi, Ani-ani ko si, Awọn t'o yipada si, Igbala ni wọn ri, Wo! Jesu Kristi jiya, Igi l'a kan An mọ, Wo! ẹjẹ Rẹ ti o san, Wo! ro! ma dẹsẹ mọ. Jesu, agbelebu Rẹ ni, N ó kan ẹsẹ mi mọ; Labẹ agbelebu Rẹ, N ó wẹ ẹsẹ mi nu, Nigba ti emi o ri Ọ Ni ọrun rere Rẹ; Ń ki yoo dẹkun yin Ọ. F'ofo at'ọla Rẹ. AMIN

Hymn 313 – OLORUN fe araye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia