Hymn 294 – W'Olori Alufa Giga | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "W'Olori Alufa Giga" (C&S Hymn #294, Yoruba). W'Olori Alufa Giga, B'o ti gbe ẹbẹ wa lọ; L'ọgba, o f'ikẹdun wolẹ, O f…

Hymn 294 – W'Olori Alufa Giga | C&S Yoruba Hymnary
W'Olori Alufa Giga, B'o ti gbe ẹbẹ wa lọ; L'ọgba, o f'ikẹdun wolẹ, O f 'ẹru dojubolẹ; Angẹli f'idamu duro, Lati ri Ẹlẹda bẹ; Awa o ha wa l'aigbọgbẹ, T'a mọ pe tori wa ni? mf Kiki ẹjẹ Jesu nikan, L'o le yi ọkan pada; Oun l'o le gba wa n'nu ẹbi, Oun l'o le m'ọkan wa rọ; Ofin at' ikilọ ko to, Wọn ko si le nikan se; Ero yi l'o le m'ọkan ro; Oluwa ku dipo mi! Jesu, gbogbo itunu wa, Lat'ọdọ Rẹ l'o ti n wa; Ifẹ, gbogbo, 'reti, suuru, Gbogbo rẹ l'ẹjẹ Rẹ ra; Lat' inu ẹkun Re l'a n gba, A ko da ohun kan ni; Lọfẹ n'Iwọ ń fi wọn tọrẹ, Fun awọn t'o s'alaini. AMIN

Hymn 294 – W'Olori Alufa Giga | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia