Hymn 293 – GBOGBO ẹjẹ ẹran | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO ẹjẹ ẹran" (C&S Hymn #293, Yoruba). GBOGBO ẹjẹ ẹran, Ti pẹpẹ awọn Ju; Ko le f'ọkan l'alafia, Ko le wẹ eeri nu.…

Hymn 293 – GBOGBO ẹjẹ ẹran | C&S Yoruba Hymnary
GBOGBO ẹjẹ ẹran, Ti pẹpẹ awọn Ju; Ko le f'ọkan l'alafia, Ko le wẹ eeri nu. Kristi Ọd'aguntan, M'ẹsẹ wa gbogbo lọ; Ẹbọ t'o ni orukọ nla, T'o ju ẹjẹ wọn lọ. Mo f'igbagbọ gb'ọwọ, Le ori Rẹ ọwọn; B'ẹni t'o ronupiwada, Mo jẹwọ ẹsẹ mi. Ọkan mi n pada wo, Ẹru t'Iwọ ti ru; Nigba ti a kan Ọ mọ'gi, Ẹsẹ rẹ wa nibẹ. f Awa n yọ ni 'gbagbọ, Bi egun ti kuro; Awa yin Ọdọ-aguntan, A n kọrin ifẹ rẹ. AMIN

Hymn 293 – GBOGBO ẹjẹ ẹran | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia