Hymn 289 – 'WO t'o ku ni Kalfari | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "'WO t'o ku ni Kalfari" (C&S Hymn #289, Yoruba). 'WỌ t'o ku ni Kalfari, 'Wọ t'o mbẹbẹ f'ẹlẹsẹ, Ran mi lọwọ, nigb'aini;…
'WỌ t'o ku ni Kalfari, 'Wọ t'o mbẹbẹ f'ẹlẹsẹ, Ran mi lọwọ, nigb'aini; Jesu, gbọ 'gbe mi. Ninu Ibanujẹ mi, At'ọkan aigbagbọ mi. Em' olori ẹlẹsẹ, Gb'oju mi si Ọ. Ọta lode, ẹru n'nu, Ko s'ire kan lọwọ mi, Iwọ l'o n gb'ẹlẹsẹ la, Mo sa tọ Ọ wa. Awọn miran dẹsẹ pẹ, Wọn si ri igbala, Wọn gbọ ohun anu Rẹ, Mu mi gbọ pẹlu. Mo k'aniyan mi le Ọ, Mo si n gbadura si Ọ, Jesu, yo mi n'nu egbe, Gba mi, ki n ma ku. 'Gbati wahala ba de, Nigb' agbara idanwo, Ati lọjọ ikẹhin, Jesu, sunmọ mi. AMIN
Hymn 289 – 'WO t'o ku ni Kalfari | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia