Hymn 288 – HOSANNA s'omo Dafidi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "HOSANNA s'omo Dafidi" (C&S Hymn #288, Yoruba). HOSANNA s'ọmọ Dafidi, Hosanna, ẹ kọrin Olubukun l'Ẹni ti mbọ, L'orukọ…

Hymn 288 – HOSANNA s'omo Dafidi | C&S Yoruba Hymnary
HOSANNA s'ọmọ Dafidi, Hosanna, ẹ kọrin Olubukun l'Ẹni ti mbọ, L'orukọ Oluwa. Hosanna s'ọmọ Dafidi', L'Ẹgbẹ Angẹli n ke; Gbogbo ẹda jumọ gberin, Hosanna s'Ọba wa. Hosanna! awọn Heberu, Ja im'ọpẹ sọna, Hosanna a mu ẹbun wa, Fi tun ọna Rẹ se. T'agba t'ewe n ke Hosanna! K'ijiya Rẹ to de; Loni, a si n kọ Hosanna! B'o ti n jọba l'oke. B'O ti gba 'yin wọn nigba naa Jọ gba ẹbẹ wa yi, Lọrun ka le b'angẹl' kọrin, Hosanna s'Ọba wa. AMIN

Hymn 288 – HOSANNA s'omo Dafidi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia