Hymn 287 – GBOGB' ogo, iyin, ola | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBOGB' ogo, iyin, ola" (C&S Hymn #287, Yoruba). GBOGB' ogo, iyin, ọla Fun Ọ, Oludande, S'Ẹni t'awọn ọmọde; Kọ Hosanna…
GBOGB' ogo, iyin, ọla Fun Ọ, Oludande, S'Ẹni t'awọn ọmọde; Kọ Hosanna didun! 'Wọ! l'Ọba Israeli, Ọm' Alade Dafid, T'o wa l'Oke Oluwa, Ọba Olubukun. Gbogb' ogo, iyin, ọla, Fun Ọ, Oludande, S'ẹni t'awọn ọmọde, Kọ Hosanna didun. Ẹgbẹ awọn Maleka, Yin Ọ loke giga; Awa at'ẹda gbogbo, Si dapọ gberin na. Gbogb' ogo, iyin, ọla, Fun Ọ, Oludande, S'ẹni t'awọn ọmọde, Kọ Hosanna didun. Awọn Heberu lọ saju, Pẹlu imọ ọpẹ; Iyin, adu‘a at' orin, L'a mu wa 'waju Rẹ. Gbogb' ogo, iyin, ọla, Fun Ọ, Oludande, S'ẹni t'awọn ọmọde, Kọ Hosanna didun. mf Si Ọ saaju iya Rẹ, Wọn kọrin iyin wọn, 'Wọ t'a gbe ga nisin yii, L'a n kọrin iyin si. Gbogb' ogo, iyin, ọla, Fun Ọ, Oludande, S'ẹni t'awọn ọmọde, Kọ Hosanna didun. 'Wọ gba orin iyin wọn; Gb'adura t'a mu wa, 'Wọ ti n yọ s'ohun rere, Ọba wa Olore. Gbogb' ogo, iyin, ọla, Fun Ọ, Oludande, S'ẹni t'awọn ọmọde, Kọ Hosanna didun. AMIN Gbogb' ogo, iyin, ọla, Fun Ọ, Oludande, S'ẹni t'awọn ọmọde, Kọ Hosanna didun.
Hymn 287 – GBOGB' ogo, iyin, ola | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia