Hymn 266 – Iwo elese, Emi n fi anu pe | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Iwo elese, Emi n fi anu pe" (C&S Hymn #266, Yoruba). 1. Iwọ ẹlẹsẹ, Emi n fi anu pe Ọkan rẹ t'o ti yigbi ninu ẹsẹ; Ma…
1. Iwọ ẹlẹsẹ, Emi n fi anu pe Ọkan rẹ t'o ti yigbi ninu ẹsẹ; Ma se ba Emi ja, ma pẹ titi mọ, Ẹbẹ Ọlọrun rẹ le pari loni. 2. Ọmọ Ijọba, mas' ẹru ẹsẹ mọ; Gb' ẹbun Ẹmi Mimọ ati itunu; Ma bi Ẹmi ninu, Olukọ rẹ ni- K'a ba le se Olugbala rẹ logo. 3. Tẹmpili d'ibajẹ, ẹwa rẹ d'ile Ina pẹpẹ Ọlọrun fẹrẹ ku tan, Bi a fi ifẹ da, O si le tun ran: Mase pa 'na Ẹmi, Oluwa mbọ wa. AMIN.
Hymn 266 – Iwo elese, Emi n fi anu pe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia