Hymn 265 – Oluwa mo gbo pe, Iwo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Oluwa mo gbo pe, Iwo" (C&S Hymn #265, Yoruba). 1. Oluwa mo gbọ pe, Iwọ, Nrọ ojo 'bukun kiri; Itunu fun ọkan arẹ, Rọ…
1. Oluwa mo gbọ pe, Iwọ, Nrọ ojo 'bukun kiri; Itunu fun ọkan arẹ, Rọ ojo naa sori mi An' emi, an' emi, Rọ ojo naa sori mi. 2. mp Ma kọja, Baba Olore, Bi ẹsẹ mi tilẹ pọ; 'Wọ le fi mi silẹ, sugbọn Jẹ k'anu rẹ ba le mi An' emi, an' emi, Rọ ojo naa sori mi. 3. Ma kọja mi, Olugbala, Jẹ k' emi le rọ mọ ọ, Emi n wa oju rere Rẹ, Pe mi mọ awọn t'o n pe -- An' emi, an' emi, Rọ ojo naa sori mi. 4. Ma kọja mi, Ẹmi Mimọ, 'Wọ le la 'ju afọju; Ẹlẹri itoye Jesu, Sọrọ asẹ naa si mi -- An' emi, an' emi, Rọ ojo naa sori mi. 5. Mo ti sun fọnfọn nin' ẹsẹ, Mo bi Ọ ninu kọja; Aye ti de ọkan mi jọ, Tu mi k'o dariji mi -- An' emi, an' emi, Rọ ojo naa sori mi. 6. Ifẹ Ọlọrun ti ki yẹ, Ẹjẹ Krist' iyebiye, Ore-ọfẹ alainiwọn; Gbe gbogbo rẹ ga n'nu mi An' emi, an' emi, Rọ ojo naa sori mi. 7. Ma kọja mi dariji mi, Fa mi mọra, Oluwa; 'Gba o n f'ibukun f'ẹlomi, Masai f'ibukun fun mi An' emi, an' emi, Masai f'ibukun fun mi. AMIN
Hymn 265 – Oluwa mo gbo pe, Iwo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia