Hymn 261 – JESU, emi o fi okan mi fun O | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU, emi o fi okan mi fun O" (C&S Hymn #261, Yoruba). 1. JESU, emi o fi ọkan mi fun Ọ, Mo jẹbi, mo gbe, sugbọn 'Wọ le…
1. JESU, emi o fi ọkan mi fun Ọ, Mo jẹbi, mo gbe, sugbọn 'Wọ le gba mi; L'aye ati l'ọrun, ko sẹni bi Rẹ, Iwọ ku f'ẹlẹsẹ - f'emi na pẹlu. 2. Jesu, mo le sinmi le orukọ Rẹ, Ti Angeli wa sọ, l'ọjọ ibi Rẹ, 'Yi t'a kọ ti o han lor' agbelebu, Ti ẹlẹsẹ si ka; wọn si tẹriba. 3. Jesu, emi ko le saigbẹkẹle Ọ, Isẹ Rẹ l'aye kun f'anu at' ifẹ, Ẹlẹsẹ yi Ọ ka, adẹtẹ ri Ọ, Ko s'ẹni buruju, t'Iwọ ko le gba. 4. Jesu mo le gbẹkẹ mi le ọrọ Rẹ, Bi n o tilẹ gbọ ohun anu Rẹ ri; Gbat' Ẹmi Rẹ n tọ ni, o ti dun pọ to, Ki n sa f'ibaralẹ k'ẹkọ lẹsẹ Rẹ. 5. Jesu totọ-totọ, mo gbẹkẹle Ọ, Ẹnikẹni t'o wa, Wọ ki o ta nu; Ootọ ni 'leri Rẹ, ọwọn l'ẹjẹ Rẹ: 'Wọnyi n'igbala mi, 'Wọ l'Ọlọrun mi. AMIN
Hymn 261 – JESU, emi o fi okan mi fun O | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia