Hymn 262 – OLORUN, Baba mi, 'Wo n pe | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN, Baba mi, 'Wo n pe" (C&S Hymn #262, Yoruba). 1. ỌLỌRUN, Baba mi, 'Wọ n pe, Asako ọmọ Rẹ mọra? Iwọ o ha dariji…
1. ỌLỌRUN, Baba mi, 'Wọ n pe, Asako ọmọ Rẹ mọra? Iwọ o ha dariji mi? Mo de, mo de, jọ gba mi la. 2. A! Jesu, Iwọ n rekọja, Pẹlu ore at' agbara? 'Wọ ko ha n gbọ igbe mi bi? Mo de, mo de, saanu fun mi. 3. A! Ẹmi Mimọ Iwọ ni? Ọrẹ ti mo ti sati pẹ! 'Wọ ha n bẹbẹ fun mi sibẹ? Mo de, mo de, m'ailera le. 4. Mo de, Oluwa, ifẹ Rẹ, Ni o n rọ mi t'o si n fa mi: f Mo wolẹ lẹsẹ rẹ, ki n mọ, B'o ti dun lati jẹ Tirẹ. AMIN
Hymn 262 – OLORUN, Baba mi, 'Wo n pe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia