Hymn 260 – Elese, e yi pada | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Elese, e yi pada" (C&S Hymn #260, Yoruba). 1. Ẹlẹsẹ, ẹ yi pada, Eese ti ẹ o fi ku? Ẹlẹda yin lo n bere? T'o fẹ ki ẹ ba…

Hymn 260 – Elese, e yi pada | C&S Yoruba Hymnary
1. Ẹlẹsẹ, ẹ yi pada, Eese ti ẹ o fi ku? Ẹlẹda yin lo n bere? T'o fẹ ki ẹ ba Oun gbe, Ọran nla ni O mbi yin, Isẹ ọwọ Rẹ ni yin, A! ẹyin alailọpẹ, Eese t'ẹ o ko 'fẹ Rẹ. 2. Ẹlẹsẹ, ẹ yi pada, Eese ti ẹ fi ku? Olugbala ni n bere, Ẹni t'o gb'ẹmi yin la; Iku Rẹ y'o j'asan bi? Ẹ o tun kan mọ 'gi bi? Ẹni 'rapada, eese Ti ẹ o gan ore Rẹ? 3. Ẹlẹsẹ, ẹ yi pada, Eese ti ẹ o fi ku? Ẹmi Mimọ ni n bere, Ti n f'ọjọ gbogbo rọ yin, Ẹ ki o ha gb'ọrọ Rẹ? Ẹ o ko iye silẹ? A ti n wa yin pẹ, eese, T'ẹ n bi Ọlọrun ninu? 4. Iyemeji ha n se yin, Pe Ifẹ ni Ọlọrun? Ẹ ki o ha gb'ọrọ Rẹ, K' ẹ gba ileri rẹ gbọ? W'Oluwa yin; lọdọ yin, Jesu n sun; w'omije Rẹ, Ẹjẹ Rẹ pẹlu n ke, pe, "Eese ti ẹ o fi ku?". AMIN

Hymn 260 – Elese, e yi pada | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia