Hymn 259 – OTOSI elese, e wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OTOSI elese, e wa" (C&S Hymn #259, Yoruba). 1. OTOSI ẹlẹsẹ, ẹ wa, Wa ni wakati anu; Jesu setan lati gba yin, O kun…
1. OTOSI ẹlẹsẹ, ẹ wa, Wa ni wakati anu; Jesu setan lati gba yin, O kun f'anu at'ifẹ, O si le sẹ, O mura tan, ma foya. 2. Ẹyin alaini, ẹ wa gba Ogo Ọlọrun l'ofẹ, 'Gbagbọ totọ, 'ronu totọ, Or' ọfẹ ti o n fa wa, Wa 'dọ Jesu, alaini owo sa wa ra. 3. Ma jẹ k'ọkan yin da yin ro Mase ro ti aiyẹ yin; Gbogbo yiyẹ t'o mbere ni, 'Yi l'O fun yin; 'tansan Ẹmi l'ọkan. 4. Ẹyin t'ẹru n pa, t'aarẹ mu, T'ẹ sọnu t'ẹ si segbe, Bi ẹ duro tit' ẹ o fi san, Ẹ ki yoo wa rara: F'ẹlẹsẹ ni, Oun ko wa f'olododo. 5. Ọlọrun goke l'awọ wa, O n fi ẹjẹ Rẹ bẹbẹ: Gbe ara le patapata: Ma gbẹkẹle ohun mi? Jesu nikan l'o le s'ẹlẹsẹ l'ore. 6. Angẹli at' awọn mimọ, N kọrin 'yin Ọd'-agutan; Gbohungbohun Orukọ Rẹ, Si gba gbogbo ọrun kan: Halleluya! ẹlẹsẹ le gberin na. AMIN
Hymn 259 – OTOSI elese, e wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia