Hymn 258 – MO Kese mi le, Jesu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MO Kese mi le, Jesu" (C&S Hymn #258, Yoruba). 1. MO Kẹsẹ mi le, Jesu, Ọd' aguntan Mimọ; O ru gbogbo ẹru mi, O sọ mi…

Hymn 258 – MO Kese mi le, Jesu | C&S Yoruba Hymnary
1. MO Kẹsẹ mi le, Jesu, Ọd' aguntan Mimọ; O ru gbogbo ẹru mi, O sọ mi d'ominira; Mo ru ẹbi mi tọ wa, K'o wẹ eeri mi nu, K'ẹjẹ Rẹ iyebiye, Le sọ mi di funfun. 2. Mo k'aini mi le Jesu, Tirẹ l'ohun gbogbo; O w'arun mi gbogbo san, O r'ẹmi mi pada; Mo ko ibanujẹ mi, Ẹru at' aniyan Le Jesu, O si gba mi, O gba irora mi. 3. Mo gb'ọkan mi le Jesu, Ọkan arẹ mi yii; Ọw' ọtun Rẹ gba mi mu, Mo sinmi laya Rẹ; Mo fẹ orukọ Jesu, Emmanuẹl, Kristi; Bi orun didun yika, Ni orukọ Rẹ jẹ. 4. Mo fẹ ki n ri bi Jesu, T'ọkan Rẹ kun fun 'fẹ; Mo fẹ ki n ri bi Jesu, Ọmọ Mimọ Baba; Mo fẹ ki mba Jesu gbe, Larin ẹgbẹ mimọ; Ki n kọrin iyin titi, Orin t'Angẹli n kọ. AMIN

Hymn 258 – MO Kese mi le, Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia