Hymn 257 – JESU, nigba 'danwo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU, nigba 'danwo" (C&S Hymn #257, Yoruba). 1. JESU, nigba 'danwo, Gbadura fun mi, K' emi ma ba sẹ Ọ, Ki n si sako…

Hymn 257 – JESU, nigba 'danwo | C&S Yoruba Hymnary
1. JESU, nigba 'danwo, Gbadura fun mi, K' emi ma ba sẹ Ọ, Ki n si sako lọ; 'Gba mba siyemeji, K'O bojuwo mi; K' ẹru tab' isaju. Ma mu mi subu. 2. B'aye ba si n fa mi, Pẹlu adun rẹ; T' Ohun 'sura aye, Fẹ han mi l'emọ; Jọ mu Gatsemane, Wa s'iranti mi, Tabi irora Rẹ, Loke Kalfari. 3. B'O ba pọn mi loju, Ninu ifẹ Rẹ; Da ibukun Rẹ le; Ori ẹbọ na: Ki n f'ara mi fun Ọ, Lori pẹpẹ Rẹ; B'ara kọ ago na Igbagbọ y'o mu. 4. p 'Gba mo ba n re 'boji, Sinu ekuru; T'ogo ọrun si n kọ, Leti bebe na; N o gbẹkẹl' ootọ Rẹ, N' ijakadi 'ku; Oluwa, gb'ẹmi mi, S' iye ailopin. AMIN

Hymn 257 – JESU, nigba 'danwo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia