Hymn 256 – Bi mo ti ri: laisawawi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Bi mo ti ri: laisawawi" (C&S Hymn #256, Yoruba). 1. Bi mo ti ri: laisawawi, Sugbọn nitori ẹjẹ Rẹ, B'O si ti pe mi pe…

Hymn 256 – Bi mo ti ri: laisawawi | C&S Yoruba Hymnary
1. Bi mo ti ri: laisawawi, Sugbọn nitori ẹjẹ Rẹ, B'O si ti pe mi pe ki n wa, Olugbala, mo de. 2. p Bi mo ti ri: laiduro pẹ, Mo fẹ k'ọkan mi mọ toto, Sọdọ Rẹ t'o le wẹ mi mọ, Olugbala, mo de. 3 Bi mo ti ri, b'o tilẹ jẹ, Ija lode, ija ninu: Ẹru lode, ẹru ninu, Olugbala mo de. 4. Bi mo ti ri: osi, are, Mo si n wa, imularada; Iwọ lo le s'awotan mi, Olugbala, mo de. 5. Bi mo ti ri: 'Wọ o gba mi, 'Wọ o gba mi tọwọ-tẹsẹ, 'Tori mo gba 'leri Rẹ gbọ, Olugbala, mo de. 6. Bi mo ti ri: Ifẹ Tirẹ, Lo sẹtẹ mi patapata; Mo di Tirẹ, Tirẹ nikan, Olugbala, mo de. AMIN

Hymn 256 – Bi mo ti ri: laisawawi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia