Hymn 220 – Ajo ni aye wa yi je, e mase w'aye m'aya | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Ajo ni aye wa yi je, e mase w'aye m'aya" (C&S Hymn #220, Yoruba). 1. Ajo ni ayé wa yi jẹ, ẹ mase w'ayé m'aya, Tẹsiwaju…

Hymn 220 – Ajo ni aye wa yi je, e mase w'aye m'aya | C&S Yoruba Hymnary
1. Ajo ni ayé wa yi jẹ, ẹ mase w'ayé m'aya, Tẹsiwaju ninu ẹmi, ninu ọdun titun yi, Oluwa pese fun aini wa ninu ọdun t'a bọ si Ki 'bukun Rẹ le kari wa gbogb' ọjọ ayé wa. Awa gbagbọ pe 'Wọ mbọ wa) Lati se 'dajọ ayé. )2ce 2. Ọlọrun t'o gbọ ti Mose, t'apa ọta ko fi ka a, Ọlọrun t'o gbọ t'Elijah t'o si doju t'ọta rẹ, D'oju t'ọta t'o ń gb'ogun ti wa; fun wa n' isẹgun lori wọn, Dabobo t'ọmọde, t'agba, Ọlọrun Ọba 'Lanu Awa gbagbọ pe 'Wọ mbọ wa ) Lati se 'dajọ ayé. )2ce 3. A dupẹ lọwọ Rẹ Oluwa, fun ore Rẹ lori wa, Ninu ọdun t'a la kọja, at'ewu t'o gbe fo wa, Wa pẹlu ọmọ Ijọ Séráfù, bukun gbogbo Kérúbù, Ki gbogbo wa le jo yin Ọ, k'a le ma se ifẹ Rẹ Awa gbagbọ pe 'Wọ mbọ wa ) Lati se 'dajọ ayé. )2ce 4. Ninu aini ta bi osi, Ọlọrun saanu fun wa, Jọwọ Ọlọrun a mbẹ Ọ, k'a ma f'ebi kẹhin ayo, Iwọ ni gbogbo wa ń kigbe pe, jẹ k'a ri bukun Rẹ gba, Jehova Alliyumion, wa sisẹ Rẹ larin wa. Awa gbagbọ pe 'Wọ mbọ wa ) Lati se 'dajọ ayé. )2ce 5. Oluwa gbọ'gbe ọmọ Rẹ, f'awa eniyan Rẹ mọra, Sunmọ wa, f'ibukun fun wa, gb'adura awa ẹda Rẹ, Lọwọ ewu at'ipanilara, masai fi'sọ Rẹ sọ wa, K'awa le jẹ ọkan ninu awọn ti 'Wọ yoo gba la Awa gbagbọ pe 'Wọ mbọ wa) Lati se 'dajọ ayé. )2ce 6. Ma jẹ k'a ku s'ọwọ esu, ọkunrin a' obinrin, Jẹ ki idasi wa loni, k'o le jẹ fun Ogo Rẹ, F'Ẹmi Mimọ Rẹ fun gbogbo wa, l'esu kuro l'ọkan wa, Ki gbogbo wa le jọ jumọ ke Halleluya lọjọ naa Awa gbagbọ pe 'Wọ mbọ wa) Lati se 'dajọ ayé. )2ce 7. Ogo in fun Baba loke, ogo ni fun Ọmọ Rẹ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lailai, A juba Orukọ Mimọ Rẹ, sunmọ wa, gb'adura wa, Jẹ ki to asẹ 'bukun Rẹ, kari wa lọkọọkan. Awa gbagbọ pe 'Wọ mbọ wa ) Lati se'dajọ ayé. )2ce AMIN

Hymn 220 – Ajo ni aye wa yi je, e mase w'aye m'aya | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia