Hymn 221 – A KI gbogbo yin ku odun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "A KI gbogbo yin ku odun" (C&S Hymn #221, Yoruba). 1. A KI gbogbo yin ku ọdun, Ẹ ku ajọy' ọdun titun; Ẹ jẹ k'a sọpẹ…

Hymn 221 – A KI gbogbo yin ku odun | C&S Yoruba Hymnary
1. A KI gbogbo yin ku ọdun, Ẹ ku ajọy' ọdun titun; Ẹ jẹ k'a sọpẹ f'Oluwa T'o da Ẹmi wa si d'oni. 2 Ọpọ ọmọde at'agba, T'o ti n gbọ 'mura ajọdun yii, Ọpọlọpọ ti kọja lọ, Wọn ti filẹ bora b'asọ. 3 Ẹgbẹ agba alatunse, Ẹ ku atunse ijọ naa, Baba ọrun yoo pẹlu yin, Yoo fi yin s'agba kalẹ. 4 A ki baalẹ p'e ku ọdun Ati gbogb' awọn Ijoye, Ẹ ku itọju ilẹ yi, Oluwa yoo ran yin lọwọ. 5 Mase foya onigbagbọ Jesu yoo pese l'ọdun yi, Ẹni ko bi, iyẹn a bi, Ẹni bi tirẹ a tun la 6 B'ina ku a f'eeru b'oju. B'ọgẹdẹ ku a f'ọmọ rọpo, O daju pe b'o tilẹ pẹ, Ọmọ wa ni o rọpo wa. 7 Gbogbo alejo, a ki yin, At' awọn olufẹ ọwọn, Jesu yoo tọju ile yin, Yoo si bukun gbogbo yin. 8 A kin yin pe Ẹ ku ọdun, Ọdun titun t'a n se loni, K'Ọlọrun da ẹmi wa si, Ki gbogbo wa se t'amọdun. AMIN

Hymn 221 – A KI gbogbo yin ku odun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia