Hymn 219 – Awa yin O/ Olorun wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Awa yin O/ Olorun wa" (C&S Hymn #219, Yoruba). Awa yin Ọ/ Ọlọrun wa; awa ń jẹwọ Rẹ pe I-wọ ni Oluwa, Gbogbo ayé fi ori…
Awa yin Ọ/ Ọlọrun wa; awa ń jẹwọ Rẹ pe I-wọ ni Oluwa, Gbogbo ayé fi ori ba/lẹ fun Ọ: Baba/ayé titi lai. Iwọ ni ẹni ti gbogbo awọn Angẹli/ń kigbe pe; Ọrun ati gbogbo agbara/ ti mbẹ ninu wọn. Iwọ ni ẹni ti awọn Kérúbù ati awọn/Séráfù: kigbe pe/ Nigba gbogbo pe. Mimọ, Mimọ, Mimọ: Oluwa Ọlọrun a/wọn ọmọ-ogun: Ọrun/oun ayé kun fun ọ/la nla ti ogo Rẹ Ẹgbẹ awọn Aposteli ti/o l'ogo: yin-Ọ, Ọgba awọn Woli ti o dara: yin-Ọ Ogun awọn Ajẹriku ti/o l'ọla: yin-Ọ Ijọ mimọ eniyan Ọlọrun ni gbogbo ayé, ń jẹwọ-Rẹ: Ba/ba: ẹni ọla nla/ti ko nipẹkun Ati ọmọ Rẹ ni/kansoso: o/lọla olotọ: Ẹmi/Mimọ pẹlu: O/lutunu. Kristi, iwọ tẹwọgba a fun ara Rẹ lati gba eniyan la: Iwọ ko korira/inu wundia, Nigba ti Iwọ sẹgun oro/iku tan: Iwọ si Ijọba Ọrun Silẹ fun gbogbo a/wọn onigbagbọ Iwọ joko lọwọ otun/Ọlọrun: ninu/ogo ti Baba. Awa gbagbọ pe I/wo mbọ wa lati se/Onidajọ ọmọ- ọdọ/Rẹ lọwọ: ti Iwọ ti fi ẹjẹ Re iye/biye ra pada. Se wọn lati ka wọn kun awọn eniyan/mimọ Rẹ: ninu ogo/ti ko nipẹkun. Oluwa, gba awọn e/niyan Rẹ la: ki Iwọ ki o si fi ibukun fun awọn/eniyan ini Rẹ, Jọ/ba wọn: Ki Iwo ki o ma gbe/wọn soke lailai. Awa ń gbe/Iwọ ga; lo/jojumọ; Awa si ń fi ori balẹ ni o/rukọ Rẹ; titi ayé/ti ko nipẹkun Fiyesini/Oluwa: lati pa wa mọ lo/ni ni ailẹsẹ. Oluwa/saanu fun wa: saa-/nu fun wa Oluwa jẹ ki aanu Rẹ ki o ma/ba le wa: gẹgẹ bi awa ti Ń gbẹkẹ wa le Ọ. Oluwa, Iwọ ni mo/gbẹkẹle; lai ma jẹ ki n daamu. AMIN
Hymn 219 – Awa yin O/ Olorun wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia