Hymn 218 – ODUN titun de awa n yo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ODUN titun de awa n yo" (C&S Hymn #218, Yoruba). 1. ỌDUN titun de awa ń yọ, Tiwa to bẹ, o ju bẹ lọ, Awa 'jọ Séráfù, Ko…
1. ỌDUN titun de awa ń yọ, Tiwa to bẹ, o ju bẹ lọ, Awa 'jọ Séráfù, Ko ni gbagbe l'ọdun to lọ, K'Ọlọrun se 'yi l'ọdun re, Ẹ ku ewu Ọdun. 2. Ẹyin ọmọ 'jọ Kérúbù, K'ẹ sotitọ titi d'opin, K'ẹ mura s' adura, K'ẹ ma woju ẹnikẹni, Ẹ gbọran si agba l'ẹnu, Ẹ yẹ 'ra ọdun wo. 3. Ẹyin Ijọ Aladura, K'ẹ ranti iran ti ẹ ń ri, S'ipa iwa rere, K'ẹ mura lati d'ohun pọ, Ẹ se ara yin ni ọkan. Ẹ yẹ'ra ọdun wo. 4. Awọn ti ko gba iran gbọ, Wọn dabi akọ keferi; Wọn ko mọ 'kan s'ọkan, Bere lọwọ Jenny Winful, Ohun t'o ri k'o to bimọ, Ẹ yẹ'ra ọdun wo. 5. K'a fi keta gbogbo silẹ, K'a fẹ ọm'ẹnikeji wa, L'ọdun t'a bọ si yi, K'a ma sọrọ ẹni lẹhin, K'ija gbogbo kuro l'ona, Ẹ yẹ'ra ọdun wo. 6. Ninu ọdun t'a bọ si yi, Agan a f'ọwọ s'osun, Ọlọmọ a tun bi, Ẹni t'o jẹ gbese y'o san, Ajẹ, oso ko ni ri wa, Ẹ yẹ'ra ọdun wo. 7. Ẹ wo bi ilu wa ti ri, Ajakal' arun tun gb'ode, K'Ọlọrun mu kuro, Nipa awẹ at'adura, K'ọkan gbogbo wa nirẹpọ, Ẹ yẹ'ra ọdun wo. 8. A ko ri ra, a ko ri ta, Ko tun s'awọn alanu mọ, Owo ko si l'ode, Ibawi Ọlọrun l'eyi, K'a ronu k' a p'iwa wa da. Ẹ yẹ'ra ọdun wo. 9. Nigba t'o ba d'ọjọ 'kẹhin, Ti ọmọ ko ni mọ baba, Oluwa, ranti mi, K'a le gbọ ohun 'kẹlẹ ni, Wi pé, ma bọ, ọmọ rere, K'a gb'ade nikẹhin. AMIN
Hymn 218 – ODUN titun de awa n yo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia