Hymn 217 – JESU loruko to ga ju | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU loruko to ga ju" (C&S Hymn #217, Yoruba). 1. JESU lorukọ to ga ju, Layé a ti lọrun; Awọn Angẹli wolẹ fun, Esu,…
1. JESU lorukọ to ga ju, Layé a ti lọrun; Awọn Angẹli wolẹ fun, Esu, bẹru o sa. Ha! Ko s'ariyanjiyan mọ, Ipe miiran ko si, O daju wi pé Jesu ku, Ani f'emi ẹlẹsẹ. 2. Kérúbù ati Séráfù, Wọn yi 'tẹ Baba ka, Nigba gbogbo niwaju Rẹ, Wọn ń kọ orin iyin. 3. Olugbala sẹgun iku, Ijọba Satan fọ; Gbogbo ẹda ẹ bu sayọ, Ka yin Baba logo. 4. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ fẹran ara yin; Ifẹ ni awọn Angẹli, Fi ń sin Baba loke 5. Jesu, Olori Ijọ wa, Bukun wa layé wa; Jọwọ pese fun aini wa, K'ebi alẹ ma pa wa. 6. Jehovah Jire Ọba wa, Iyin f'orukọ Rẹ; Ma jẹ ki oso at'ajẹ Ri wa lọjọ ayé wa. 7. Jesu, fọ itẹgun esu, Iwọ l'Ọba Ogo; Iyin, ope ni fun Baba, Ni fun Mẹtalọkan. Ha! Ko s'ariyanjiyan mọ, Ipe miran ko si, O daju wi pé Jesu ku, Ani f' emi ẹlẹsẹ. AMIN
Hymn 217 – JESU loruko to ga ju | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia