Hymn 216 – MA tan irawo didan | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MA tan irawo didan" (C&S Hymn #216, Yoruba). 1. MA tan, Irawọ didan, Lat' ile Rẹ loke; Ma fi 'fẹran Baba han, 'N'nu…

Hymn 216 – MA tan irawo didan | C&S Yoruba Hymnary
1. MA tan, Irawọ didan, Lat' ile Rẹ loke; Ma fi 'fẹran Baba han, 'N'nu titan didan Rẹ. Ma tan, ma tan, Iwọ Irawọ didan, Ma tan, ma tan, Iwọ Irawọ didan. 2. Ma tan, Irawọ Ogo, A gboju wa si Ọ; Ni oke awọsanma, Awa n ri 'tansan Rẹ. Ma tan, ma tan, Iwọ Irawọ didan, Ma tan, ma tan, Iwọ Irawọ didan. 3. Ma tan, 'Wọ ti ki parọ, Ko si s'amọna wa; Sibi t'imọlẹ ayọ, Ti ko lopin gbe wa. Ma tan, ma tan, Iwọ Irawọ didan, Ma tan, ma tan, Iwọ Irawọ didan. 4. 'Gba ba si d'ọrun pẹlu, Awọn t'arapada; K'a wa pẹlu Rẹ n'nu Ogo, Le ma tan titi lai. Ma tan, ma tan, Iwọ Irawọ didan, Ma tan, ma tan, Iwọ Irawọ didan. AMIN

Hymn 216 – MA tan irawo didan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia