Hymn 215 – KI gbogbo ojubo oro d'oko | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "KI gbogbo ojubo oro d'oko" (C&S Hymn #215, Yoruba). 1. KI gbogbo ojubọ oro d'oko, T'Ọya, t'Ogun ati t'Esu, Ki wọn…

Hymn 215 – KI gbogbo ojubo oro d'oko | C&S Yoruba Hymnary
1. KI gbogbo ojubọ oro d'oko, T'Ọya, t'Ogun ati t'Esu, Ki wọn dojubọ Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. Oluwa, se wa ni Tirẹ, Tirẹ sa ni wa titi ayé, Nitori Kristi Ọmọ Baba, Da wa si n'Ijọ Séráfù. 2. Ki gbogbo ojubọ Irumọlẹ Ti Sangó ati sanponna, Ki wọn dojubọ Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. 3. Ki gbogbo ojubọ Irumọlẹ, T'Ifa ati t'Ọbaluayé, Ki wọn dojubọ Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. 4. Ki gbogbo ojubọ 'risa loko, Ti babaji ati osun, Ki wọn dojubọ Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. 5. K'awọn agbagba le yipada, Ati Ọba Osemọwe, Ki wọn le juba Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. 6. Ki gbogbo ojubọ Ọlọrun, Ti 'Gunnu ati Gelede, Ki wọn dojubọ Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. 7. K'awọn Keferi le yipada, At'awọn Elegun pẹlu, Ki wọn le juba Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. 8. K'awọn ọlọya le yipada, At'awọn alagẹmo, Ki wọn le juba Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. 9. Ki gbogbo ọmọ 'jọ Séráfù, At'Ijọ Kérúbù pẹlu, Ki wọn le juba Jesu Ọba, L'adura Ijọ Séráfù. 10. Ki gbogb' awọn Ẹgbẹ Akọrin, Ati Ẹgbẹ Aladura Ki Ẹgbẹ Igbimọ Séráfù, Ki wọn d'amure wọn giri. 11. K'Ọlọrun da alagba wa si, Ati awọn Isọngbe rẹ K'Ọlọrun tubo ran yin lọwọ, K'O di yin l'amure ododo. 12. K'a fi ogo fun Baba l'oke, K'a f'ogo fun Ọmọ pẹlu, K'a fi ogo fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan l'ọpẹ yẹ fun. Oluwa, se wa ni Tirẹ, Tirẹ sa ni wa titi ayé, Nitori Kristi Ọmọ Baba, Da wa si n'Ijọ Séráfù. AMIN

Hymn 215 – KI gbogbo ojubo oro d'oko | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia