Hymn 214 – E funpe naa kikan | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E funpe naa kikan" (C&S Hymn #214, Yoruba). 1. Ẹ funpe naa kikan, Ipe ihinrere, K'o dun jake jado, L'eti gbogbo ẹda:…

Hymn 214 – E funpe naa kikan | C&S Yoruba Hymnary
1. Ẹ funpe naa kikan, Ipe ihinrere, K'o dun jake jado, L'eti gbogbo ẹda: Ọdun idasilẹ ti de; Pada ẹlẹsẹ pada. 2. Fun 'pe t'Ọdaguntan; T'a ti pa s'etutu, Jẹ ki agbayé mọ, Agbara ẹjẹ Rẹ, 3. Ẹyin ẹru ẹsẹ, Ẹ so'ra yin d'ọmọ, Lọwọ Kristi Jesu, Ẹ gb'ominira yin. 4. Olori Alufa, L'Olugbala ise; O fi 'ra Rẹ rubọ, Arukun, aruda. 5. mf Ọkan alarẹ, wa, Sinmi laya Jesu, p Onirobinujẹ, Tujuka, si ma yọ. AMIN

Hymn 214 – E funpe naa kikan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia