Hymn 208 – OJO ayo nlanla naa de | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJO ayo nlanla naa de" (C&S Hymn #208, Yoruba). 1. ỌJỌ ayọ nlanla naa de, Eyi t'arayé ti ń reti; Nigba t'Olugbala…

Hymn 208 – OJO ayo nlanla naa de | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌJỌ ayọ nlanla naa de, Eyi t'arayé ti ń reti; Nigba t'Olugbala w'ayé Nigba t'a bi ninu ara. 2. Olus' aguntan ni papa, Bi wọn ti ń sọ aguntan wọn, Ni ihin ayọ naa ko ba, Ihin bibi Olugbala. 3. Angẹl iransẹ Oluwa, L'a ran si wọn, alabukun, Pẹlu ogo t'o ń tan julọ, Lati sọ ihin ayọ yi. 4. mp Gidigidi l'ẹru ba wọn, Fun ajeji iran nla yi; Ma bẹru l'ọrọ iyanju, T'o t'ẹnu Angẹli wa. 5. A bi Olugbala loni, Kristi Oluwa ayé ni; N'ilu nla Dafidi l'O wa, N'ibujẹ ẹran l'a tẹ si. 6. Ogo fun Ọlọrun‖ l'orin, Ti eniyan y'o kọ s'ọrun; Fun ifẹ Rẹ laini opin, T'o mu alafia w'ayé. AMIN

Hymn 208 – OJO ayo nlanla naa de | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia