Hymn 207 – ONIGBAGBO, e bu s'ayo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ONIGBAGBO, e bu s'ayo" (C&S Hymn #207, Yoruba). 1. ONIGBAGBỌ, ẹ bu s'ayọ, Ọjọ nla l'eyi fun wa: Ẹ gbọ bi awọn Angẹli,…

Hymn 207 – ONIGBAGBO, e bu s'ayo | C&S Yoruba Hymnary
1. ONIGBAGBỌ, ẹ bu s'ayọ, Ọjọ nla l'eyi fun wa: Ẹ gbọ bi awọn Angẹli, Ti ń fi Ogun fun Ọlọrun, Alafia, Alafia, Ni fun gbogbo eniyan. 2. Ki gbogbo ayé ho f'ayọ: K'a f'ogo fun Ọlọrun; Ọmọ bibi Rẹ l'O fun wa; T'a bi ninu Wundia, Ẹn' Iyanu, Ni ọmọ t'a bi loni. 3. Ninu gbogbo rudurudu, Ohun ibi t'o kun ayé, Ninu idamu nla ẹsẹ, L'Ọm'Ọlọrun wa gba wa: Olugbimọ, Olugbimọ, Alade alafia. 4. Ọlọrun Olodumare; L'a bi, bi ọmọ titun; Baba! Ẹni ayérayé; L'o di alakoso wa; Ẹ bu s'ayọ, Ẹ bu s'ayọ, Ọmọ Dafidi jọba. 5. O wa gba wa lọwọ ẹsẹ, O wa d'onigbọwọ wa, Lati fọ itẹgun ẹsẹ, A se ni Ọga Ogo: Ẹ ku ayọ, ẹ ku ayọ, A gba wa lọwọ iku. AMIN

Hymn 207 – ONIGBAGBO, e bu s'ayo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia