Hymn 209 – AJIN jin, oru mimo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "AJIN jin, oru mimo" (C&S Hymn #209, Yoruba). 1. AJIN jin, oru mimọ, Okun su, 'mọlẹ de, Awọn Olus'aguntan ń sọna, Ọmọ…

Hymn 209 – AJIN jin, oru mimo | C&S Yoruba Hymnary
1. AJIN jin, oru mimọ, Okun su, 'mọlẹ de, Awọn Olus'aguntan ń sọna, Ọmọ titun t'o wa l'oju orun. Sinmi n'nu alafia, Sinmi n'nu alafia. 2. Ajin jin, oru mimọ, Mọlẹ de, okun sa, Olusọ aguntan gb'orin Angẹli, Kabiyesi Alleluya Ọba. Jesu Olugbala de, Jesu Olugbala de. 3. Ajin jin, oru mimọ, 'Rawọ ọrun tan 'mọlẹ, Wo awọn Amoye ila orun, Mu ọrẹ wọn wa fun Ọba wa. Jesu Olugbala de, Jesu Olugbala de. 4. Ajin jin, oru mimọ, 'Rawọ, ọrun tan 'mọlẹ, Ka pẹlu awọn Angẹli kọrin, Kabiyesi Alleluya Ọba. Jesu Olugbala de, Jesu Olugbala de. AMIN

Hymn 209 – AJIN jin, oru mimo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia