Hymn 201 – WA, eyin oloto | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "WA, eyin oloto" (C&S Hymn #201, Yoruba). 1. WA, ẹyin olotọ, L'ayọ at'isẹgun, Wa k'a lọ, wa ka lọ si Betlehem, Wa ka lọ…
1. WA, ẹyin olotọ, L'ayọ at'isẹgun, Wa k'a lọ, wa ka lọ si Betlehem, Wa ka lọ wo o! Ọba awọn Angẹl! Ẹ wa ka lọ juba Rẹ, Ẹ wa ka lọ juba Rẹ, Ẹ wa k'a lọ juba Kristi Oluwa. 2. Olodumare ni! Imọlẹ Ododo, Ko si korira inu Wundia; Ọlọrun papa ni, T'a bi, t'a ko da. 3. Angẹli, ẹ kọrin, Kọrin itoye Rẹ, Ki gbogbo ẹda ọrun si gberin, Ogo f'Ọlọrun, L'oke ọrun l'ọhun: 4. Nitotọ, a wolẹ, F'Ọba t'a bi loni; Jesu Iwọ ni awa ń fi ogo fun, 'Wọ ọmọ Baba, T'o gbe ara wa wọ! Ẹ wa ka lọ juba Rẹ, Ẹ wa ka lọ juba Rẹ, Ẹ wa k'a lọ juba Kristi Oluwa. AMIN
Hymn 201 – WA, eyin oloto | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia