Hymn 202 – NIGBA kan ni Betlehemu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "NIGBA kan ni Betlehemu" (C&S Hymn #202, Yoruba). 1. NIGBA kan ni Betlehemu, Ile kekere kan wa; Nib'iya kan tẹ 'mọ rẹ…

Hymn 202 – NIGBA kan ni Betlehemu | C&S Yoruba Hymnary
1. NIGBA kan ni Betlehemu, Ile kekere kan wa; Nib'iya kan tẹ 'mọ rẹ si, Lori ibujẹ ẹran; Maria n'iya ọmọ naa, Jesu Kristi l'ọmọ naa. 2. O t'ọrun wa sode ayé, Oun ni Ọlọrun Oluwa, O f'ile ẹran se ile, 'Bujẹ ẹran fun 'busun; L'ọdọ awọn otosi, Ni Jesu gbe ni ayé. 3. Ni gbogbo igba ewe Rẹ, O gbọran o si mb'ọla; O fẹran o si ń tẹriba, Fun iya ti ń tọju Rẹ; O yẹ ki gbogb' ọmọde, Ko se Olugbọran bẹ. 4. 'Tori Oun jẹ awose wa, A ma dagba bi awa; O kere ko le da nkan se, p A ma sọkun bi awa; O si le ba wa daro, f O le ba wa yọ pẹlu. 5. A o f'oju wa ri nikẹhin, Ni agbara ifẹ Rẹ; Nitori ọmọ rere yi, Ni Oluwa wa l'ọrun, O ń tọ awa ọmọ Rẹ, S'ọna ibi ti Oun lọ. 6. Ki se ni ibujẹ ẹran, Nibi ti malu ń jeun; L'awa o ri sugbọn l'ọrun, L'ọwọ ọtun Ọlọrun, 'Gba wọn 'mọ Rẹ b'irawọ, Ba ń tan nin' asọ ala. AMIN

Hymn 202 – NIGBA kan ni Betlehemu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia