Hymn 200 – Eyin Angel' l'orun ogo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Eyin Angel' l'orun ogo" (C&S Hymn #200, Yoruba). 1. Ẹyin Angẹl' l'ọrun ogo, To yi gbogbo ayé ka; Ẹ ti kọrin dida ayé,…
1. Ẹyin Angẹl' l'ọrun ogo, To yi gbogbo ayé ka; Ẹ ti kọrin dida ayé, Ẹ so t'ibi Messia; Ẹ wa jọsin, ẹ wa jọsin, Fun Kristi Ọba titun. 2. Ẹyin Olusọ-aguntan, Ti ń sọ ẹran yin loru Emmanueli wa ti de, Irawọ ọmọ naa ń tan. 3. Onigbagbọ ti ń tẹriba, Ni 'bẹru at'ireti, L'ojiji l'Oluwa o de, Ti yoo mu yin re'le 4. Ẹlẹsẹ 'wọ alaironu, Ẹlẹbi ati egbe, Ododo Ọlọrun duro, Anu ń pe ọ, pa 'wa da. 5. Gbogbo ẹda ẹ fo f'ayọ, Jesu Olugbala de, Anfani miran ko si mọ, B'eyi ba fo yin kọja. Njẹ, ẹ wa sin, Njẹ ẹ wa sin, Sin Kristi Ọba Ogo. AMIN
Hymn 200 – Eyin Angel' l'orun ogo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia